Ìdí rèé tí àwọn aláwo kò fi sin òkú Murphy Afolabi

您所在的位置:网站首页 1 sinx平方的原函数 Ìdí rèé tí àwọn aláwo kò fi sin òkú Murphy Afolabi

Ìdí rèé tí àwọn aláwo kò fi sin òkú Murphy Afolabi

2023-05-25 21:20| 来源: 网络整理| 查看: 265

Ìdí rèé tí àwọn aláwo kò fi sin òkú Murphy AfolabiMurphy Afolabi

Oríṣun àwòrán, Murphy Afolabi/Instagram

wákàtí kan sẹ́yìn

Awọn ẹri tuntun ti jade lori iru ẹsin ti gbajumọ oṣere, Murphy Afolabi ṣe ko to o ku.

Lẹyin iku rẹ ni iroyin jade pe o wa ninu ẹgbẹ awo ko to o ku.

Waheeb Ibrahim to jẹ aburo oloogbe Murphy Afolabi sọ fun ileeṣẹ amohunmaworan GBOAH TV pe awọn ko gbọ iroyin pe boya o rẹ Murphy, iroyin iku rẹ nikan ni awọn gbọ́.

Ọgbẹni Ibrahim sọrọ lori awuyewuye kan to waye ṣaaju ki wọn o to o sin oku oloogbe Afolabi.

Lara awuyewuye to waye ni bi Alfa kan ṣe ni oun ko le sin oku tabi kirun si oku Murphy, nitori pe aláwo ni.

Bakan naa ni awọn kan gbagbọ pe bi ẹbi rẹ ṣe kọkọ ni ki wọn o gbe oku rẹ wa si agboole wọn niluu Osogbo fun isinku, niiṣe pẹlu pe o wa lati idile onífá.

Awọn kan ti ẹ sọ pe awọn aláwo ni yoo sin oku rẹ.

Ṣugbọn ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe nibi eto adura ọjọ kẹjọ ti wọn ṣe fun oloogbe ni agboole wọn, Alfa Ibrahim ṣalaye iru eeyan ti Murphy jẹ ninu ẹ̀sìn.

O ni “Murphy gan-an-gan ni Ifa, ti ko si si awo to tun fẹ ṣe mọ lẹyin eyi.

O ṣalaye pe nigba ti awọn wadii lẹnu aburo rẹ kan ti oun naa n gbe niluu Eko, lati mọ boya awọn ni yoo sin oku Murphy, o ni ẹni naa jẹ ko ye awọn pe “Murphy ko ba awọn alawo Eko ṣe”.

“Bakan naa ni awọn alawo ni ile (Osogbo) nigba ti a beere lọwọ wọn , sọ pe Murphy ko ba awọn ṣe.”

Èrò àwọn ọmọ Naijiria ṣe ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí gbèsè tí àwọn Alfa sọ pé Adunni Ade jẹ Murphy Afolabiwákàtí 6 sẹ́yìnÀwọn ọlọ́pàá ti sọ̀rọ̀sókè fún Òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Fakunle lórí ìṣẹ̀lẹ̀ 'Tear gas' tó wáyé ní Osogbo lánàáwákàtí 6 sẹ́yìn

Alfa Ibrahim tẹsiwaju pe, iroyin ti awọn gbọ gẹgẹ bi ẹbi ni pe lati ọdun 2022 ni Murphy Afolabi ti n ki ìrun gẹgẹ bi musulumi.

“Koda wọn sọ fun wa pe o gba awẹ (Ramadan) lọdun to kọja, to si tun ṣe gudugudu meje ati yaaya mẹfa ninu awẹ ọdun yii.”

O ni idi niyii ti awọn alawo ko fi le sin oku rẹ, nitori o fojuhan pe o ti di musulumi.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo ọhun lo tun ti mẹnuba a pe ọdun mẹwaa ni oloogbe Murphy Afolabi fi kọ iṣẹ awo niluu Oyo.

O ni inu ẹsin Islam ni Murphy ku si, eyi ti ko fi nii si aburu kankan nitori pe awọn alawo kọ lo sin oku rẹ.

Àwọn èèyàn máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí èdè ẹ̀nu mi ṣùgbọ́n bí màá ṣe sọ̀rọ̀ di ọjọ́ ikú nìyí – Murphy Afolabi, nínú ọ̀rọ̀ tó sọ gbẹ̀yìn pẹ̀lú BBC18 Èbibi 2023Èmi àti Murphy sọ̀rọ̀ ni àgó mẹ́san-an àbọ̀, ó ṣubú ni àgó mẹ́wàá àlẹ̀ - Golugo17 Èbibi 2023"Baba to bi Murphy Afolabi lo kọ agbaọjẹ awo, Ifayemi Elebuibon niṣẹ awo

Iroyin to tẹ Ileeṣẹ BBC lọwọ ni pe Baba Murphy Afolabi lọ kọ Agbaọjẹ ninu awo sise Baba Ifayemi Elebuibon nisẹ awo tí Murphy Afolabi naa si pada lọ kọ isẹ awo parí lọdọ Baba Ifayemi Elebubon gẹgẹ bí awọn mọlẹbí ni agboole wọn ṣe ṣalaye.

Baba Murphy Afolabi lo ọgọfa ọdun le mẹrin (124years) laye ko to kú.

Murphy Afọlabi ṣalaye fun BBC ninu ifọrọwanilẹnuwo kan lọdun 2021 pe, ere itage ti agba oṣere ati agbaṣaga, Oloye Ifayẹmi Ẹlẹbubọn maa n ṣe kaakiri ilu Osogbo nigba naa ni o gbin irugbin ifẹ ere itage ati iṣẹ sinima si ọkan oun tofi di eyi to gbẹrẹgẹjigẹ ti gbogbo aye fi mọ oun.

O ni igba ti oun de ilu Eko loun darapọ mọ ẹgbẹ oṣere Ọgbẹni Fasasi Ọlabankẹwin ti ọpọ m si Dagunro Alakija oogun.



【本文地址】


今日新闻


推荐新闻


CopyRight 2018-2019 办公设备维修网 版权所有 豫ICP备15022753号-3